-
Jóṣúà 23:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 “Torí náà, ẹ jẹ́ onígboyà gidigidi kí ẹ lè máa pa gbogbo ohun tí a kọ sínú ìwé Òfin+ Mósè mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé e, kí ẹ má ṣe yà kúrò nínú rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì,+ 7 ẹ má ṣe bá àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ́ kù pẹ̀lú yín yìí ṣe wọlé-wọ̀de.+ Ẹ ò tiẹ̀ gbọ́dọ̀ dárúkọ àwọn ọlọ́run wọn,+ ẹ ò gbọ́dọ̀ fi wọ́n búra, ẹ ò gbọ́dọ̀ sìn wọ́n láé, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún wọn.+
-
-
Jeremáyà 12:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 “Tí wọ́n bá sì sapá láti kọ́ ọ̀nà àwọn èèyàn mi, tí wọ́n sì fi orúkọ mi búra pé, ‘Bí Jèhófà ti wà láàyè!’ bí àwọn náà ṣe kọ́ àwọn èèyàn mi láti máa fi Báálì búra, ìgbà náà ni wọn yóò rí àyè láàárín àwọn èèyàn mi.
-
-
Sefanáyà 1:4, 5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 “Màá na ọwọ́ mi sórí Júdà
Àti sórí gbogbo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù,
Gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn tó ń sin* Báálì+ ní ibí yìí ni màá sì pa rẹ́,
Àti orúkọ àwọn àlùfáà ọlọ́run àjèjì pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn àlùfáà míì,+
5 Àti àwọn tó ń forí balẹ̀ lórí òrùlé fún àwọn ọmọ ogun ọ̀run+
Àti àwọn tó ń forí balẹ̀, tí wọ́n ń jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ti Jèhófà+ làwọn ń ṣe
Lẹ́sẹ̀ kan náà, tí wọ́n ń jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ti Málíkámù làwọn ń ṣe;+
-