12 Jèhóákínì ọba Júdà jáde lọ bá ọba Bábílónì,+ òun àti ìyá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀;+ ọba Bábílónì sì mú un lẹ́rú ní ọdún kẹjọ ìṣàkóso rẹ̀.+
14 Ó kó gbogbo Jerúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn, gbogbo ìjòyè,+ gbogbo jagunjagun tó lákíkanjú àti gbogbo oníṣẹ́ ọnà pẹ̀lú gbogbo oníṣẹ́ irin,*+ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) èèyàn ló kó lọ sí ìgbèkùn. Kò ṣẹ́ ku ẹnì kankan àfi àwọn aláìní ní ilẹ̀ náà.+