-
Ìsíkíẹ́lì 21:21, 22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Torí ọba Bábílónì dúró ní oríta náà, níbi tí ọ̀nà ti pín sí méjì, kó lè woṣẹ́. Ó mi àwọn ọfà. Ó wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn òrìṣà* rẹ̀; ó fi ẹ̀dọ̀ woṣẹ́. 22 Nígbà tó woṣẹ́, ohun tó rí ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ darí wọn sí Jerúsálẹ́mù, pé kí wọ́n gbé igi tí wọ́n fi ń fọ́ ògiri, kí wọ́n pàṣẹ láti pa ọ̀pọ̀, kí wọ́n kéde ogun, kí wọ́n gbé igi tí wọ́n fi ń fọ́ ògiri ti àwọn ẹnubodè, kí wọ́n mọ òkìtì yí i ká láti dó tì í, kí wọ́n sì fi iyẹ̀pẹ̀ mọ odi yí i ká.+
-