8 Ní oṣù karùn-ún, ní ọjọ́ keje oṣù náà, ìyẹn ní ọdún kọkàndínlógún Nebukadinésárì ọba Bábílónì, Nebusarádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́, ìránṣẹ́ ọba Bábílónì, wá sí Jerúsálẹ́mù.+ 9 Ó dáná sun ilé Jèhófà+ àti ilé ọba+ pẹ̀lú gbogbo ilé tó wà ní Jerúsálẹ́mù;+ ó tún sun ilé gbogbo àwọn ẹni ńlá.+