16 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:
“Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún yín.+
Wọ́n ń tàn yín ni.
Ìran tó wá láti inú ọkàn wọn ni wọ́n ń sọ,+
Kì í ṣe láti ẹnu Jèhófà.+
17 Léraléra ni wọ́n ń sọ fún àwọn tí kò bọ̀wọ̀ fún mi pé,
‘Jèhófà ti sọ pé: “Ẹ máa ní àlàáfíà.”’+
Wọ́n sì ń sọ fún gbogbo ẹni tó ní agídí ọkàn pé,
‘Àjálù kankan kò ní bá yín.’+