10 Jóṣúà sì sọ pé: “Báyìí lẹ ṣe máa mọ̀ pé Ọlọ́run alààyè kan wà láàárín yín,+ ó sì dájú pé ó máa lé àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Hífì, àwọn Pérísì, àwọn Gẹ́gáṣì, àwọn Ámórì àti àwọn ará Jébúsì kúrò níwájú yín.+
26 Mo pàṣẹ pé ní gbogbo ibi tí mo ti ń ṣàkóso, kí àwọn èèyàn máa bẹ̀rù Ọlọ́run Dáníẹ́lì gidigidi.+ Torí òun ni Ọlọ́run alààyè, ó sì máa wà títí láé. Ìjọba rẹ̀ ò ní pa run láé, àkóso* rẹ̀ sì máa wà títí ayérayé.+