25 “Mo ti gbọ́ ohun tí àwọn wòlíì tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi sọ, pé, ‘Mo lá àlá! Mo lá àlá!’+26 Ìgbà wo ni àwọn wòlíì ò ní yéé sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké tó wà lọ́kàn wọn? Wọ́n jẹ́ àwọn wòlíì tó ń sọ ẹ̀tàn inú ọkàn wọn.+
21 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí nípa Áhábù ọmọ Koláyà àti nípa Sedekáyà ọmọ Maaseáyà, àwọn tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún yín ní orúkọ mi,+ ‘Wò ó, màá fi wọ́n lé ọwọ́ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, á sì pa wọ́n lójú yín.