-
Ìsíkíẹ́lì 16:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 “‘Àmọ́ ẹwà rẹ mú kí o bẹ̀rẹ̀ sí í jọ ara rẹ lójú,+ o sì di aṣẹ́wó torí òkìkí rẹ ti kàn káàkiri.+ Gbogbo àwọn tó ń kọjá lọ lo bá ṣèṣekúṣe,+ ẹwà rẹ sì di tiwọn. 16 O mú lára àwọn ẹ̀wù rẹ, o sì ṣe àwọn ibi gíga aláràbarà tí o ti ń ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó.+ Kò yẹ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wáyé, kò tiẹ̀ yẹ kó ṣẹlẹ̀ rárá.
-