-
2 Àwọn Ọba 23:29, 30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Nígbà ayé rẹ̀, Fáráò Nẹ́kò ọba Íjíbítì wá bá ọba Ásíríà lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Yúfírétì, Ọba Jòsáyà sì jáde lọ kò ó lójú; àmọ́ nígbà tí Nẹ́kò rí i, ó pa á ní Mẹ́gídò.+ 30 Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi kẹ̀kẹ́ ẹṣin gbé òkú rẹ̀ láti Mẹ́gídò wá sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì sin ín sí sàréè rẹ̀. Lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn ilẹ̀ náà mú Jèhóáhásì ọmọ Jòsáyà, wọ́n fòróró yàn án, wọ́n sì fi í jọba ní ipò bàbá rẹ̀.+
-