5 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni Jèhóákímù+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlá (11) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.+ 6 Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì wá dojú kọ ọ́, kó lè fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà méjì dè é láti mú un lọ sí Bábílónì.+