-
Jeremáyà 7:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Ẹ tún ọ̀nà yín àti ìwà yín ṣe, màá sì jẹ́ kí ẹ máa gbé ibí yìí.+
-
-
Jeremáyà 36:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Bóyá nígbà tí àwọn ará ilé Júdà bá gbọ́ nípa gbogbo àjálù tí mo fẹ́ mú bá wọn, wọ́n á lè yí pa dà kúrò nínú ìwà ibi wọn, kí n sì dárí àṣìṣe wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n.”+
-
-
Jónà 3:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ta ló mọ̀ bóyá Ọlọ́run tòótọ́ máa pèrò dà* nípa ohun tó ní lọ́kàn, kó sì yí ìbínú rẹ̀ pa dà, ká má bàa ṣègbé?”
-