11 Nígbà tí Mikáyà ọmọ Gemaráyà ọmọ Ṣáfánì gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà nínú àkájọ ìwé náà, 12 ó lọ sí ilé ọba, sí yàrá akọ̀wé. Gbogbo àwọn ìjòyè jókòó síbẹ̀: Élíṣámà+ akọ̀wé, Deláyà ọmọ Ṣemáyà, Élínátánì+ ọmọ Ákíbórì,+ Gemaráyà ọmọ Ṣáfánì, Sedekáyà ọmọ Hananáyà àti gbogbo àwọn ìjòyè yòókù.