18 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Wò ó, màá kó àwọn tó lọ sí oko ẹrú láti àgọ́ Jékọ́bù jọ,+
Máa sì ṣojú àánú sí àwọn àgọ́ ìjọsìn rẹ̀.
Wọ́n á tún ìlú náà kọ́ sórí òkìtì rẹ̀,+
Ibi tó sì yẹ ni wọ́n á kọ́ ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò sí.
19 Ìdúpẹ́ àti ohùn ẹ̀rín á ti ọ̀dọ̀ wọn wá.+
Màá sọ wọ́n di púpọ̀, wọn ò sì ní kéré níye;+
Màá mú kí wọ́n pọ̀ níye,
Wọn ò sì ní jẹ́ ẹni yẹpẹrẹ.+