14 tí àwọn èèyàn mi tí à ń fi orúkọ mi pè+ sì rẹ ara wọn sílẹ̀,+ tí wọ́n gbàdúrà, tí wọ́n wá ojú mi, tí wọ́n sì kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú wọn,+ nígbà náà, màá gbọ́ láti ọ̀run, màá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, màá sì wo ilẹ̀ wọn sàn.+
27 nítorí pé ọlọ́kàn tútù ni ọ́,* tí o rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run bí o ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ tó sọ nípa ibí yìí àti àwọn tó ń gbé ibẹ̀, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú mi, tí o fa aṣọ rẹ ya, tí o sì sunkún níwájú mi, èmi náà ti gbọ́ ohun tí o sọ,+ ni Jèhófà wí.