13 torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Màá tún na ọwọ́ mi láti fìyà jẹ Édómù, èmi yóò pa àwọn èèyàn àti ẹran ọ̀sìn ibẹ̀, èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro.+ Idà ni yóò pa wọ́n láti Témánì títí dé Dédánì.+
15 Bí inú yín ṣe dùn nígbà tí ogún ilé Ísírẹ́lì di ahoro, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe sí yín.+ Ìwọ yóò di ahoro, ìwọ agbègbè olókè Séírì, àní gbogbo Édómù;+ wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”