-
Jeremáyà 4:30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 Ní báyìí tí o ti di ahoro, kí lo máa ṣe?
O ti máa ń wọ aṣọ rírẹ̀dòdò tẹ́lẹ̀,
O ti máa ń fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ṣe ara rẹ lóge,
O sì ti máa ń fi tìróò* sọ ojú rẹ di ńlá.
-
-
Ìsíkíẹ́lì 16:37Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
37 torí náà, èmi yóò kó gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ tí ẹ jọ gbádùn ara yín jọ, gbogbo àwọn tí o fẹ́ràn àti àwọn tí o kórìíra. Màá kó wọn jọ láti ibi gbogbo kí wọ́n lè bá ọ jà, màá sì tú ọ sí ìhòòhò lójú wọn, wọ́n á sì rí ìhòòhò rẹ.+
-