-
Ìsíkíẹ́lì 40:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Yàrá ẹ̀ṣọ́ mẹ́ta ló wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ẹnubodè tó wà ní ìlà oòrùn. Ìwọ̀n mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dọ́gba, ìwọ̀n àwọn òpó tó wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì sì dọ́gba.
-
-
Ìsíkíẹ́lì 43:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
43 Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ẹnubodè tó dojú kọ ìlà oòrùn.+
-
-
Ìsíkíẹ́lì 46:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
46 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Kí ẹnubodè àgbàlá inú tó dojú kọ ìlà oòrùn+ wà ní títì pa+ fún ọjọ́ mẹ́fà tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́,+ àmọ́ kí wọ́n ṣí i ní ọjọ́ Sábáàtì àti ọjọ́ òṣùpá tuntun. 2 Ìjòyè náà máa gba ibi àbáwọlé*+ ẹnubodè náà wọlé láti ìta, yóò sì dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ilẹ̀kùn ẹnubodè náà. Àwọn àlùfáà yóò rú odindi ẹbọ sísun rẹ̀ àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rẹ̀, yóò sì tẹrí ba níbi ẹnubodè náà, yóò wá jáde. Àmọ́ kí wọ́n má ti ẹnubodè ibẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́.
-