-
Àìsáyà 6:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ní ọdún tí Ọba Ùsáyà kú,+ mo rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́ gíga, tó sì ta yọ,+ etí aṣọ rẹ̀ kún inú tẹ́ńpìlì. 2 Àwọn séráfù dúró lókè rẹ̀; ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìyẹ́ mẹ́fà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan* fi méjì bo ojú, ó fi méjì bo ẹsẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì ń fi méjì fò kiri.
3 Ọ̀kan sì ń sọ fún èkejì pé:
“Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.+
Ògo rẹ̀ kún gbogbo ayé.”
-