21 Igun mẹ́rin ni àwọn férémù ibi mímọ́ náà ní.+ Ohun kan wà níwájú ibi mímọ́ náà tó dà bíi 22 pẹpẹ onígi+ tí gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta, tí gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì. Ó ní igun, igi ni wọ́n sì fi ṣe ìsàlẹ̀ rẹ̀ àti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Ó wá sọ fún mi pé: “Tábìlì tó wà níwájú Jèhófà nìyí.”+