-
Léfítíkù 21:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Sọ fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Áárónì pé, ‘Ẹnikẹ́ni nínú yín ò gbọ́dọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ torí ẹni* tó kú láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+ 2 Àmọ́ ó lè ṣe bẹ́ẹ̀ tí ẹni náà bá jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tó sún mọ́ ọn, ìyá rẹ̀, bàbá rẹ̀, ọmọkùnrin rẹ̀, ọmọbìnrin rẹ̀ tàbí arákùnrin rẹ̀, 3 ó sì lè fi arábìnrin rẹ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, tó bá jẹ́ wúńdíá tó wà nítòsí rẹ̀, tí kò sì tíì lọ́kọ.
-