24 Hẹsikáyà ọba Júdà wá fi ẹgbẹ̀rún kan (1,000) akọ màlúù àti ẹgbẹ̀rún méje (7,000) àgùntàn ṣe ọrẹ fún ìjọ náà, àwọn ìjòyè sì fi ẹgbẹ̀rún kan (1,000) akọ màlúù àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àgùntàn ṣe ọrẹ fún ìjọ náà;+ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlùfáà sì ń ya ara wọn sí mímọ́.+