2 Ìjòyè náà máa gba ibi àbáwọlé+ ẹnubodè náà wọlé láti ìta, yóò sì dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ilẹ̀kùn ẹnubodè náà. Àwọn àlùfáà yóò rú odindi ẹbọ sísun rẹ̀ àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rẹ̀, yóò sì tẹrí ba níbi ẹnubodè náà, yóò wá jáde. Àmọ́ kí wọ́n má ti ẹnubodè ibẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́.