4 Bí mo ṣe ń wò, mo rí i tí ìjì líle+ ń fẹ́ bọ̀ láti àríwá, ìkùukùu* ńlá wà níbẹ̀, iná* sì ń kọ mànà, ìmọ́lẹ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò+ yí i ká, ohun kan sì wà nínú iná náà tó ń tàn yanran bí àyọ́pọ̀ wúrà àti fàdákà.+
27 Mo sì rí ohun kan tó ń dán yanran bí àyọ́pọ̀ wúrà àti fàdákà,+ ó rí bí iná, ó jọ pé ó ń jó látibi ìbàdí rẹ̀ lọ sókè; mo rí ohun kan tó dà bí iná+ láti ìbàdí rẹ̀ lọ sísàlẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ sì tàn yòò yí i ká