2 Mo rí ọkùnrin mẹ́fà tí wọ́n ń bọ̀ láti ẹnubodè apá òkè,+ tó dojú kọ àríwá, kálukú mú ohun ìjà tí wọ́n fi ń fọ́ nǹkan dání; ọkùnrin kan wà lára wọn tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀, ìwo yíǹkì akọ̀wé sì wà ní ìbàdí rẹ̀. Wọ́n wọlé, wọ́n sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ bàbà.+