3 Ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ wá gbéra lórí àwọn kérúbù níbi tó wà tẹ́lẹ̀, lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé náà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pe ọkùnrin tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, tí ìwo yíǹkì akọ̀wé wà ní ìbàdí rẹ̀.
4 Ògo Jèhófà+ gbéra láti orí àwọn kérúbù wá sí ẹnu ọ̀nà ilé náà, ìkùukùu sì bẹ̀rẹ̀ sí í kún inú ilé náà díẹ̀díẹ̀,+ ògo Jèhófà sì mọ́lẹ̀ yòò ní gbogbo àgbàlá náà.