-
Ìsíkíẹ́lì 33:30, 31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, àwọn èèyàn rẹ ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ nípa rẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ògiri àti ní ẹnu ọ̀nà àwọn ilé.+ Wọ́n ń sọ fún ara wọn, kálukú ń sọ fún arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.’ 31 Wọn yóò rọ́ wá bá ọ, kí wọ́n lè jókòó síwájú rẹ bí èèyàn mi; wọ́n á sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, àmọ́ wọn ò ní ṣe ohun tí wọ́n gbọ́.+ Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ dídùn fún ọ,* àmọ́ bí wọ́n ṣe máa jèrè tí kò tọ́ ló wà lọ́kàn wọn.
-