-
Ìsíkíẹ́lì 16:36, 37Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
36 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Torí pé ìṣekúṣe rẹ ti hàn sí gbangba, ìhòòhò rẹ sì ti hàn síta nígbà tí ò ń bá àwọn olólùfẹ́ rẹ ṣèṣekúṣe, tí o sì ń bá àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* rẹ+ tó ń ríni lára ṣèṣekúṣe, àwọn tí o tún fi ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ rẹ rúbọ sí,+ 37 torí náà, èmi yóò kó gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ tí ẹ jọ gbádùn ara yín jọ, gbogbo àwọn tí o fẹ́ràn àti àwọn tí o kórìíra. Màá kó wọn jọ láti ibi gbogbo kí wọ́n lè bá ọ jà, màá sì tú ọ sí ìhòòhò lójú wọn, wọ́n á sì rí ìhòòhò rẹ.+
-