-
1 Àwọn Ọba 10:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Nígbà náà, ọbabìnrin Ṣébà gbọ́ bí ìròyìn Sólómọ́nì ṣe ń gbé ògo orúkọ Jèhófà yọ,+ torí náà, ó wá láti fi àwọn ìbéèrè* tó ta kókó dán an wò.+ 2 Ó dé Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn abọ́barìn* tó gbayì,+ pẹ̀lú àwọn ràkúnmí tó ru òróró básámù+ àti wúrà tó pọ̀ gan-an àti àwọn òkúta iyebíye. Ó lọ sọ́dọ̀ Sólómọ́nì, ó sì bá a sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀.
-
-
Àìsáyà 60:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Gbogbo àwọn tó wá láti Ṣébà, wọ́n máa wá;
Wọ́n máa gbé wúrà àti oje igi tùràrí.
Wọ́n máa kéde ìyìn Jèhófà.+
-