19 Àmọ́ tí o bá kìlọ̀ fún ẹni burúkú tí kò sì jáwọ́ nínú iṣẹ́ ibi àti ìwà burúkú rẹ̀, yóò kú torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó dájú pé ìwọ yóò gba ẹ̀mí* rẹ là.+
6 Àmọ́ nígbà tí wọn ò yéé ṣàtakò sí i, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ láìdáa, ó gbọn ẹ̀wù rẹ̀,+ ó sì sọ fún wọn pé: “Kí ẹ̀jẹ̀ yín wà lórí ẹ̀yin fúnra yín.+ Ọrùn mi mọ́.+ Láti ìsinsìnyí lọ, màá lọ máa bá àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè.”+