18 Tí mo bá sọ fún ẹni burúkú pé, ‘Ó dájú pé wàá kú,’ àmọ́ tí ìwọ kò kìlọ̀ fún un, tí ìwọ kò sì kìlọ̀ fún ẹni burúkú náà pé kó jáwọ́ nínú ìwà burúkú rẹ̀ kó lè wà láàyè,+ yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ torí pé ó jẹ́ ẹni burúkú,+ àmọ́ ọwọ́ rẹ ni màá ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.+