37 Ìwọ ọba, ọba àwọn ọba, tí Ọlọ́run ọ̀run ti fún ní ìjọba,+ agbára, okun àti ògo, 38 tó sì ti fi àwọn èèyàn lé lọ́wọ́, ibi yòówù kí wọ́n máa gbé, títí kan àwọn ẹranko orí ilẹ̀ àtàwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, tó sì fi ṣe ọba lórí gbogbo wọn,+ ìwọ fúnra rẹ ni orí wúrà náà.+