16 Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ nípa rẹ pé o lè sọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀,+ o sì lè wá ojútùú sí ohun tó bá lọ́jú pọ̀. Tí o bá lè ka ọ̀rọ̀ yìí, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, a máa fi aṣọ aláwọ̀ pọ́pù wọ̀ ọ́, a máa fi ìlẹ̀kẹ̀ wúrà sí ọ lọ́rùn, o sì máa di igbá kẹta nínú ìjọba.”+