31 Torí ó ti dá ọjọ́ kan tó máa fi òdodo ṣèdájọ́ + ayé láti ọwọ́ ọkùnrin kan tó ti yàn, ó sì ti pèsè ẹ̀rí tó dájú fún gbogbo èèyàn bó ṣe jí i dìde kúrò nínú ikú.”+
12 Mo rí àwọn òkú, ẹni ńlá àti ẹni kékeré, wọ́n dúró síwájú ìtẹ́ náà, a sì ṣí àwọn àkájọ ìwé sílẹ̀. Àmọ́ a ṣí àkájọ ìwé míì; àkájọ ìwé ìyè ni.+ A fi àwọn ohun tí a kọ sínú àkájọ ìwé náà ṣèdájọ́ àwọn òkú bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ṣe rí.+