8 Wọ́n fèsì pé: “Kálukú wa lá àlá, àmọ́ kò sẹ́ni tó máa túmọ̀ rẹ̀ fún wa.” Jósẹ́fù sọ fún wọn pé: “Ṣebí Ọlọ́run+ ló ni ìtúmọ̀? Ẹ jọ̀ọ́, ẹ rọ́ àlá yín fún mi.”
17 Ọlọ́run tòótọ́ fún àwọn ọ̀dọ́* mẹ́rin yìí ní ìmọ̀ àti òye nínú oríṣiríṣi ìkọ̀wé àti ọgbọ́n; ó sì fún Dáníẹ́lì ní òye láti túmọ̀ onírúurú ìran àti àlá.+