2 Ọba Nebukadinésárì wá ránṣẹ́ sí àwọn baálẹ̀, àwọn aṣíwájú, àwọn gómìnà, àwọn agbani-nímọ̀ràn, àwọn olùtọ́jú ìṣúra, àwọn adájọ́, àwọn agbófinró àti gbogbo àwọn alábòójútó ìpínlẹ̀ pé kí wọ́n kóra jọ, kí wọ́n wá síbi ayẹyẹ tí wọ́n fẹ́ fi ṣí ère tí Ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀.