-
Dáníẹ́lì 3:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Ní báyìí, tí ẹ bá gbọ́ ìró ìwo, fèrè ape, ọpọ́n orin olókùn púpọ̀, háàpù onígun mẹ́ta, ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín, fèrè alápò awọ àti gbogbo ohun ìkọrin míì, ohun tó máa dáa ni pé kí ẹ ṣe tán láti wólẹ̀, kí ẹ sì jọ́sìn ère tí mo ṣe. Àmọ́ tí ẹ bá kọ̀ láti jọ́sìn, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n máa jù yín sínú iná ìléru tó ń jó. Ta sì ni ọlọ́run tó lè gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ mi?”+
-