35 Kódà nígbà tí wọ́n wà lábẹ́ ìjọba ti ara wọn, tí wọ́n sì ń gbádùn ọ̀pọ̀ ohun rere tí o fún wọn, tí wọ́n ń gbé lórí ilẹ̀ tó fẹ̀, tó sì lọ́ràá* tí o fi jíǹkí wọn, wọn ò sìn ọ́,+ wọn ò sì jáwọ́ nínú ìwà búburú tí wọ́n ń hù.
4 “‘Ẹ má dà bí àwọn baba yín, tí àwọn wòlíì àtijọ́ kéde fún pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fi ìwà búburú yín sílẹ̀* kí ẹ sì jáwọ́ nínú iṣẹ́ ibi.’”’+
“‘Àmọ́ wọn ò gbọ́, wọn ò sì fetí sí ohun tí mo sọ,’+ ni Jèhófà wí.