-
2 Kíróníkà 26:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Yàtọ̀ síyẹn, Ùsáyà kọ́ àwọn ilé gogoro+ sí Jerúsálẹ́mù lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ẹnubodè Igun+ àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ẹnubodè Àfonífojì+ àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ìtì Ògiri, ó sì mú kí wọ́n lágbára. 10 Ó tún kọ́ àwọn ilé gogoro+ sí aginjù, ó sì gbẹ́ kòtò omi púpọ̀* (nítorí ó ní ẹran ọ̀sìn tó pọ̀ gan-an); ó ṣe bákan náà ní Ṣẹ́fẹ́là àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀.* Ó ní àwọn àgbẹ̀ àti àwọn tó ń rẹ́wọ́ àjàrà ní àwọn òkè àti ní Kámẹ́lì, nítorí ó fẹ́ràn iṣẹ́ àgbẹ̀.
-