-
Ẹ́sírà 9:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Mo sọ pé: “Ìwọ Ọlọ́run mi, ojú ń tì mí, ara sì ń tì mí láti gbé ojú mi sókè sí ọ, ìwọ Ọlọ́run mi, nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ti pọ̀ gan-an lórí wa, ẹ̀bi wa sì ti ga dé ọ̀run.+
-
-
Dáníẹ́lì 9:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Jèhófà, tìrẹ ni òdodo, àmọ́ àwa ni ìtìjú bá, bó ṣe rí lónìí yìí, àwa èèyàn Júdà, àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti gbogbo Ísírẹ́lì, àwọn tó wà nítòsí àti lọ́nà jíjìn, ní gbogbo ilẹ̀ tí o fọ́n wọn ká sí torí pé wọn ò jẹ́ olóòótọ́ sí ọ.+
-