17 Jèhófà Ọlọ́run wa ló mú àwa àti àwọn bàbá wa kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ kúrò ní ilé ẹrú,+ òun ló ṣe àwọn iṣẹ́ àmì tó kàmàmà yìí níṣojú wa,+ tó sì ń ṣọ́ wa ní gbogbo ọ̀nà tí a rìn àti lọ́dọ̀ gbogbo àwọn èèyàn tí a gba àárín wọn kọjá.+
8 “Gbàrà tí Jékọ́bù dé sí Íjíbítì,+ tí àwọn baba ńlá yín sì bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́,+ Jèhófà rán Mósè+ àti Áárónì, kí wọ́n lè mú àwọn baba ńlá yín jáde kúrò ní Íjíbítì, kí wọ́n sì mú kí wọ́n máa gbé ibí yìí.+