2 Ó jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù,+
Ọjọ́ ìkùukùu àti ìṣúdùdù tó kàmàmà,+
Bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀ lórí àwọn òkè.
Àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n pọ̀, tí wọ́n sì lágbára;+
Kò tíì sí irú wọn rí,
Irú wọn kò sì ní sí mọ́ láé,
Jálẹ̀ àwọn ọdún láti ìran dé ìran.