-
Ìṣe 2:16-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí a gbẹnu wòlíì Jóẹ́lì sọ ni pé: 17 ‘“Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ni Ọlọ́run wí, “èmi yóò tú lára ẹ̀mí mi sára onírúurú èèyàn,* àwọn ọmọ yín lọ́kùnrin àti lóbìnrin yóò máa sọ tẹ́lẹ̀, àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín yóò máa rí ìran, àwọn àgbà ọkùnrin yín yóò sì máa lá àlá,+ 18 kódà, èmi yóò tú lára ẹ̀mí mi sára àwọn ẹrúkùnrin mi àti sára àwọn ẹrúbìnrin mi ní àwọn ọjọ́ náà, wọ́n á sì máa sọ tẹ́lẹ̀.+
-