-
2 Kíróníkà 21:16, 17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Lẹ́yìn náà, Jèhófà gbé+ àwọn Filísínì*+ àti àwọn ará Arébíà+ tó wà nítòsí àwọn ará Etiópíà dìde sí Jèhórámù. 17 Nítorí náà, wọ́n ya bo Júdà, wọ́n sì fi ipá wọ inú rẹ̀, wọ́n kó gbogbo ohun ìní tó wà nínú ilé* ọba,+ wọ́n tún kó àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìyàwó rẹ̀; ọmọ kan ṣoṣo tó ṣẹ́ kù fún un ni Jèhóáhásì,*+ àbíkẹ́yìn rẹ̀.
-
-
Jóẹ́lì 3:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Kí ló dé tí ẹ fi ṣe báyìí sí mi,
Tírè, Sídónì àti gbogbo ilẹ̀ Filísíà?
Ṣé mo ṣẹ̀ yín ni tí ẹ fi ń gbẹ̀san?
Tó bá jẹ́ ẹ̀san lẹ̀ ń gbà,
Ṣe ni màá yára dá a pa dà sórí yín láìjáfara.+
-