-
Émọ́sì 6:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 “‘“Bí ó bá sì ṣẹ́ ku ọkùnrin mẹ́wàá sínú ilé kan, àwọn náà máa kú. 10 Mọ̀lẹ́bí* kan á wá gbé wọn jáde, á sì sun wọ́n lọ́kọ̀ọ̀kan. Á kó egungun wọn jáde kúrò nínú ilé; á sì béèrè lọ́wọ́ ẹni tó bá wà ní àwọn yàrá inú pé, ‘Ṣé wọ́n ṣì kù lọ́dọ̀ rẹ?’ Ẹni náà á fèsì pé, ‘Kò sí ẹnì kankan!’ Nígbà náà, á sọ pé, ‘Dákẹ́! Nítorí kì í ṣe àkókò yìí ló yẹ ká máa pe Jèhófà.’”
-