-
Dáníẹ́lì 9:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Gbogbo Ísírẹ́lì ti tẹ Òfin rẹ lójú, wọ́n sì ti yà kúrò nínú rẹ̀ torí pé wọn ò ṣègbọràn sí ohùn rẹ, tí o fi da ègún àti ìbúra lé wa lórí, èyí tí wọ́n kọ sínú Òfin Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́,+ torí pé a ti ṣẹ̀ Ẹ́. 12 Ó ti ṣe ohun tó sọ lòdì sí àwa+ àti àwọn alákòóso wa tí wọ́n jọba lé wa lórí,* torí ó mú kí àjálù ńlá ṣẹlẹ̀ sí wa; ohunkóhun ò ṣẹlẹ̀ rí lábẹ́ gbogbo ọ̀run bí èyí tó ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù.+
-
-
Émọ́sì 4:12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Torí náà, màá tún fìyà jẹ ọ́, ìwọ Ísírẹ́lì.
Nítorí ohun tí màá ṣe sí ọ yìí,
Múra sílẹ̀ láti pàdé Ọlọ́run rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì.
-