16 Àwọn tó rí ọ máa tẹjú mọ́ ọ;
Wọ́n máa yẹ̀ ọ́ wò fínnífínní, wọ́n á sọ pé,
‘Ṣé ọkùnrin tó ń mi ayé tìtì nìyí,
Tó kó jìnnìjìnnì bá àwọn ìjọba,+
17 Tó mú kí ilẹ̀ ayé tí à ń gbé dà bí aginjù,
Tó sì gba àwọn ìlú rẹ̀,+
Tí kò jẹ́ kí àwọn ẹlẹ́wọ̀n rẹ̀ pa dà sílé?’+