3 “Ní báyìí, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerúsálẹ́mù àti ẹ̀yin èèyàn Júdà,
Ẹ jọ̀ọ́, ẹ ṣèdájọ́ láàárín èmi àti ọgbà àjàrà mi.+
4 Kí ló tún yẹ kí n ṣe fún ọgbà àjàrà mi
Tí mi ò tíì ṣe?+
Nígbà tí mo retí pé kó so èso àjàrà,
Kí ló dé tó jẹ́ àjàrà igbó nìkan ló ń mú jáde?