29 Nígbà ayé rẹ̀, Fáráò Nẹ́kò ọba Íjíbítì wá bá ọba Ásíríà lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Yúfírétì, Ọba Jòsáyà sì jáde lọ kò ó lójú; àmọ́ nígbà tí Nẹ́kò rí i, ó pa á ní Mẹ́gídò.+
22 Síbẹ̀, Jòsáyà kò pa dà lẹ́yìn rẹ̀, ńṣe ló para dà+ láti lọ bá a jà, kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ Nékò, èyí tó wá láti ẹnu Ọlọ́run. Torí náà, ó wá jà ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Mẹ́gídò.+