-
Ìṣe 10:37, 38Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
37 Ẹ mọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ nípa rẹ̀ káàkiri gbogbo Jùdíà, bẹ̀rẹ̀ láti Gálílì+ lẹ́yìn ìrìbọmi tí Jòhánù wàásù: 38 nípa Jésù tó wá láti Násárẹ́tì, bí Ọlọ́run ṣe fi ẹ̀mí mímọ́+ àti agbára yàn án, tí ó sì lọ káàkiri ilẹ̀ náà, tí ó ń ṣe rere, tí ó sì ń wo gbogbo àwọn tí Èṣù ń ni lára sàn,+ torí pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.+
-