-
Lúùkù 12:58, 59Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
58 Bí àpẹẹrẹ, tí ìwọ àti ẹni tó fẹ̀sùn kàn ọ́ lábẹ́ òfin bá ń lọ sọ́dọ̀ alákòóso kan, sapá láti yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú rẹ̀ lójú ọ̀nà, kó má bàa mú ọ wá síwájú adájọ́, kí adájọ́ wá fi ọ́ lé òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ lọ́wọ́, kí òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ sì jù ọ́ sẹ́wọ̀n.+ 59 Mò ń sọ fún ọ pé, ó dájú pé o ò ní kúrò níbẹ̀ títí wàá fi san ẹyọ owó kékeré tó kù* tí o jẹ́.”
-